Forum Index Forums GENERAL Motivation Iṣẹ́ AJÍMẸ́FUN, Iṣẹ́ àṣejèrè

Viewing 0 reply threads
  • Author
    Posts
    • #49822
      Avatar of Tijani SalamTijani Salam
      Participant

      *AJÍMẸ́FUN*

      Iṣẹ́ AJÍMẸ́FUN, Iṣẹ́ àánú
      Iṣẹ́ AJÍMẸ́FUN, Iṣẹ́ àṣejèrè
      Iṣẹ́ AJÍMẸ́FUN, Iṣẹ́ atóríṣe.
      Iṣẹ́ Ọ̀làjú, Iṣẹ́ àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n.
      Iṣẹ́ Olùkọ́ wù mí yéye!

      Olórí kíkú kì í ṣe é
      Ọlọ́pọlọ pípé ní ṣiṣẹ́ ẹfun
      Ọ̀mọ̀wé ènìyàn,
      Ní í ṣiṣẹ́ Olùkọ́
      Gbogbo olórí kíkú ọmọ
      Ló ti d’ọlọ́pọlọ pípé ọmọ
      Láti ipasẹ̀ Olùkọ́

      Gbogbo akékọ̀ọ́ tí kò nímọ̀ rárá
      Ṣe bí Olùkọ ló bu omi ọgbọ́n fún wọn mu?
      Tí wọ́n d’ẹni tó jáfáfá
      Tí wọ́n d’ẹni tó lóye!
      Tí wọ́n d’èèyàn àtàtà láwùjọ
      Iṣẹ takuntakun ni Olùkọ́ ń se.

      Iṣẹ́ Olùkọ́!
      Iṣẹ́ àṣelà
      Iṣẹ́ olùkọ́!
      Iṣẹ́ ìdùnnú ni
      Ta ló ń f’ẹnu sáátá iṣẹ́ olùkọ́?
      Asínwín ènìyàn ní pe olùkọ́ lólè.

      Gbogbo òbí tó bá fojú tẹ́ńbẹ́lú wo Tísà láyé,
      Kò fẹ́ k’ọ́mọ rẹ̀ níláárí láyé nù un.
      Òbí tó bá r’Ólùkọ́ fín,
      Yóò dá ọmọ rẹ̀ kọ́ ní kọ̀rọ̀ yàrá.

      Ẹ jẹ́ ká gb’ọ́lá fún gbogbo AJÍMẸ́FUN
      Ẹ jẹ́ ká ṣè’bà fún gbogbo Olùkọ́ àwa.
      Mo fẹ́ d’adájọ́
      Mo fẹ́ di dókítà
      Kò ṣe é f’ẹnu lásán jẹ́
      Láìgba iwájú Olùkọ́ kọjá.

      B’éèyàn yóò di Ààrẹ Orílẹ̀-èdè láyé,
      Iwájú Olùkọ́ ni yóò ti bu omi ọgbọ́n mu.
      Gbogbo ẹni di Gómìnà lónìí
      Ti b’omi ọgbọ́n mu lọ́wọ́ AJÍMẸ́FUN.

      *ORIN*
      Àdúrà mẹ́ta ló yẹ Tísà mi; (2x)
      Kó lówó, kó sì rérè jẹ.
      K’ẹni ẹlẹ́ni má gbàṣe rẹ̀ ṣe.
      Kó tún re ìlú òyìnbó ooooo.

      Igi eléso jìngbìnnì; (2x)
      Tísà ló so dókítà
      ÈGBÈ: Igi eléso jìngbìnnì
      Tísà ló so lọ́yà.
      ÈGBÈ: Igi eléso jìngbìnnì
      Tísà ló so báńkà.
      ÈGBÈ:Igi eléso jìngbìnnì.

      *If you are a teacher, appreciate yourself.*

      *God bless all our teachers*
      . Good morning

Viewing 0 reply threads
  • You must be logged in to reply to this topic.
Scroll to Top